12 Pẹlupẹlu Abiṣai ọmọ Seruiah pa ẹgbãsan ninu awọn ara Edomu li afonifoji Iyọ̀.
13 O si fi ẹgbẹ-ogun si Edomu: ati gbogbo awọn ara Edomu si di iranṣẹ Dafidi. Bayi li Oluwa ngbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
14 Bẹ̃ ni Dafidi jọba lori gbogbo Israeli, o si ṣe idajọ ati otitọ larin awọn enia rẹ̀.
15 Joabu ọmọ Seruiah si wà lori ogun; ati Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọwe-iranti.
16 Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Abimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; ati Ṣafṣa ni akọwe;
17 Benaiah ọmọ Jehoiada li o si wà lori awọn Kereti ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si li olori lọdọ ọba.