17 Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.
18 Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni.
19 Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u.
20 Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli.
21 Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u.
22 Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi.
23 Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.