9 Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe,
10 Lọ ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, mo fi nkan mẹta lọ̀ ọ: yàn ọkan ninu wọn ki emi ki o le ṣe e si ọ.
11 Bẹ̃ni Gadi tọ Dafidi wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, yan fun ara rẹ,
12 Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi.
13 Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia.
14 Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia.
15 Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.