1 WỌNYI li awọn ọmọ Dafidi, ti a bi fun u ni Hebroni; akọbi Amnoni, lati ọdọ Ahinoamu ara Jesreeli; ekeji Danieli, lati ọdọ Abigaili ara Karmeli;
2 Ẹkẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Gesuri; ẹkẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti.
3 Ẹkarun, Ṣefatiah lati ọdọ Abitali; ẹkẹfa Itreamu lati ọdọ Ẹgla aya rẹ̀.
4 Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
5 Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli: