66 Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.
67 Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀,
68 Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀,
69 Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:
70 Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.
71 Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀,
72 Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,