12 Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.
13 Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha.
14 Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi:
15 Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin.
16 Maaka, obinrin Makiri, bi ọmọ, on si pè orukọ rẹ̀ ni Pereṣi: orukọ arakunrin rẹ̀ ni Ṣereṣi; ati awọn ọmọ rẹ̀ ni Ulamu ati Rakemu.
17 Awọn ọmọ Ulamu: Bedani. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse.
18 Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala.