5 Ati awọn arakunrin wọn ninu gbogbo idile Issakari jẹ akọni alagbara enia, ni kikaye gbogbo wọn nipa iran wọn, nwọn jẹ ẹgbamẹtalelogoji o le ẹgbẹrun.
6 Awọn ọmọ Benjamini: Bela, ati Bekeri, ati Jediaeli, mẹta.
7 Awọn ọmọ Bela; Esboni, ati Ussi, ati Ussieli ati Jerimoti ati Iri, marun; awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia; a si kaye wọn nipa iran wọn si ẹgbãmọkanla enia o le mẹrinlelọgbọ̀n.
8 Awọn ọmọ Bekeri: Semira, ati Joaṣi, ati Elieseri, ati Elioeni, ati Omri, ati Jeremotu, ati Abiah, ati Anatoti, ati Alameti. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Bekeri.
9 Ati iye wọn, ni idile wọn nipa iran wọn, awọn olori ile baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbawa o le igba.
10 Awọn ọmọ Jediaeli; Bilhani: ati awọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi, ati Benjamini, ati Ehudi, ati Kenaana, ati Setani, ati Tarṣiṣi ati Ahisahari.
11 Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.