1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Húsì, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jóòbù; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú,
2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un.
3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin (7000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ìbákasíẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọdámàlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀ jù gbogbo àwọn ará ìlà òòrun lọ.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn.