11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹnibúburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;ó sì dì mí ọrùn mú, ó sì gbọ̀nmí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ ṣe àmì—ìtàfàsí rẹ̀.
13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mikákiri; ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò sidásí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;ó súré kọlù mi bí jagunjagun.
15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ n bò ara mi, mosì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikúsì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
17 Kì í ṣe nítorí àìsòótọ́ kan ní ọwọ́mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.