8 Ìwọ sì fi ìkiyẹ̀jẹ kùn mí lára, tí ójẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó yọ lára mi, ó jẹ́rìí lòdì sí ojú mi.
9 Ọlọ́run fi Ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ósì ṣọ̀tá mi; ó pa eyín rẹ̀ keke sími, ọ̀ta mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yán sí mi;Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbáẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹnibúburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;ó sì dì mí ọrùn mú, ó sì gbọ̀nmí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ ṣe àmì—ìtàfàsí rẹ̀.
13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mikákiri; ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò sidásí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;ó súré kọlù mi bí jagunjagun.