21 Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.
22 Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ.
23 Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run,
24 o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú.
25 Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa sìn. N óo pèsè ọpọlọpọ nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu fún yín, n óo sì mú àìsàn kúrò láàrin yín.
26 Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́.
27 “N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín.