9 Mose dá Farao lóhùn pé, “Sọ ìgbà tí o fẹ́ kí n gbadura fún ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati àwọn eniyan rẹ, kí Ọlọrun lè run gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ yín, ati ninu ilé yín; kí ó sì jẹ́ pé kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”
10 Ọba dáhùn pé, “Ní ọ̀la.”Mose bá wí pé, “Bí o ti wí gan-an ni yóo rí, kí o lè mọ̀ pé kò sí ẹlòmíràn tí ó dàbí OLUWA Ọlọrun wa.
11 Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, ati ninu àwọn ilé rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ; kìkì odò Naili nìkan ni ọ̀pọ̀lọ́ yóo kù sí.”
12 Mose ati Aaroni bá jáde kúrò níwájú Farao, Mose gbadura sí OLUWA pé kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà kúrò, gẹ́gẹ́ bí òun ati Farao ti jọ ṣe àdéhùn.
13 OLUWA ṣe ohun tí Mose fi adura bèèrè, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí wọ́n wà ninu gbogbo ilé, ati ní àgbàlá, ati ní gbogbo oko sì kú.
14 Wọ́n kó wọn jọ ní òkítì òkítì, gbogbo ìlú sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn.
15 Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.