13 Ṣe giri ki o si jẹ ki a huwa akọni fun enia wa ati fun ilu Ọlọrun wa: ki Oluwa ki o si ṣe eyi ti o dara loju rẹ̀.
14 Bẹ̃ni Joabu ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀ sún siwaju awọn ara Siria si ibi ija: nwọn si sá niwaju rẹ̀.
15 Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn pẹlu sá niwaju Abiṣai arakunrin rẹ̀, nwọn si wọ̀ ilu lọ. Nigbana ni Joabu wá si Jerusalemu.
16 Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn.
17 A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà.
18 Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na.
19 Nigbati awọn iranṣẹ Hadareseri ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ba Dafidi làja, nwọn si nsìn i: bẹ̃ni awọn ara Siria kò jẹ ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.