1 NJẸ bi a ti pín awọn ọmọ Aaroni ni wọnyi. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.
2 Ṣugbọn Nadabu ati Abihu kú ṣaju baba wọn, nwọn kò si li ọmọ: nitorina ni Eleasari ati Itamari fi ṣiṣẹ alufa.
3 Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn.
4 A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn.
5 Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.