1 Ìran sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù èyí tí Àìṣáyà ọmọ Ámọ́sì rí ní àsìkò ìjọba Hùṣáyà, Jótamù, Áhásì àti Heṣekáyà àwọn ọba Júdà.
2 Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!Nítorí Olúwa ti sọrọ̀:“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
3 Màlúù mọ olówó rẹ̀,kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì kò mọ̀,òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”
4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,Ìran àwọn aṣebi,àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì,wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
5 Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.