Àìsáyà 64 BMY

1 Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2 Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3 Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.

4 Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

5 Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọnń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́,tí ó rántí ọ̀nà rẹ.Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,inú bí ọ.Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?

6 Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,gbogbo òdodo wa sì dàbí èkíṣà ẹlẹ́gbin;gbogbo wa kákò bí ewé,àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

7 Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹtàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún waó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8 Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.Àwa ni amọ̀, ìwọ ni ọ̀mọ;gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

9 Má ṣe bínú kọjá ààlà, Ìwọ Olúwa:Má ṣe rántíi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.

10 Àwọn Ìlú Mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;Ṣíhónì pàápàá aṣálẹ̀ ni, Jérúsálẹ́mù ibi ìkọ̀sílẹ̀.

11 Tẹ́ḿpìlì Mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,ni a ti fi iná sun,àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.

12 Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọó ha sì tún fara rẹ pamọ́ bí?Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹwá kọjá ààlà bí?