Àìsáyà 33 BMY

Ìpọ́njú Àti Ìrànlọ́wọ́

1 Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,ìwọ tí a kò tí ì pa ọ́ run!Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń panirun;a ó pa ìwọ náà run,nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,a ó da ìwọ náà.

2 Olúwa ṣàánú fún waàwa ń ṣàfẹ́ríi rẹ.Má a jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.

3 Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀ èdè fọ́nká.

4 Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórègẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú.

5 A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6 Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

7 Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréréẹkún ní òpópónà;àwọn ikọ̀ àlàáfíà ṣunkún kíkorò.

8 Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣátì,kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nàA ti ba àdéhùn jẹ́,a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9 Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,ojú ti Lẹ́bánónì ó sì ṣáṢárónì sì dàbí aginjù,àti Báṣánì òun Kámẹ́lì rẹ àwọn èwe wọn.

10 “Ní ìsinsìn yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.“Ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi ga,ní ìsinsìn yìí ni a ó gbé mi sókè.

11 Ìwọ lóyún fùfùléèléè,o sì bí koríko;èémí rẹ iná ni tí ó ń jó ọ run.

12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jínjìn, gbọ́ ohuntí mo ti ṣe;Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

14 Èrù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Ṣíhónì;ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú ìjóná àìnípẹ̀kun?”

15 Ẹni tí ó ń rìn lódodotí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,tí ó kọ èrè tí ó tibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etíi rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàntí ó sì di ojúu rẹ̀ sí àtipète ibi

16 ọkùnrin náà nìyìí tí yóò gbé ní ibi gíga,ẹni tí ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.A ó máa mú àkàrà rẹ̀ wábẹ́ẹ̀ ni omi kì yóò wọ́n ọn.

17 Ojúu rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.

18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:“Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójú tó ilé-ìṣọ́ wà?”

19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn wọ̀nyẹn mọ́,àwọn ènìyàn tí èdè wọn farasin,pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yéni.

20 Gbójú ṣókè sí Ṣíhónì, ìlú àjọ̀dún wa,ojú rẹ yóò rí Jérúsálẹ́mù,ibùgbé àlàáfíà nnì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtutàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.

21 Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa.Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèkéé.Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lóríi wọn,ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.

22 Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni olófin wa, Olúwa òun ni ọba wa;òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.

23 Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pínàní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.

24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Ṣíhónì tí yóòwí pé, “èmi ń sàìsàn,”àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ni a ó fojúfòdá.