Àìsáyà 50 BMY

Ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì Àti Ìgbọ́ràn Ìráńṣẹ́

1 Ohun tí Olúwa wí níyìí:“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ìyá rẹ wàèyí tí mo fi lé e lọ?Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mini mo tà ọ́ fún?Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.

2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun,Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omiwọ́n sì kú fún òùngbẹ.

3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀mo sì fi aṣọ-ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”

4 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.O jí mi láràárọ̀,o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.

5 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sí mi ní etí,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;Èmi kò sì padà ṣẹ́yìn.

6 Mo sí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irúngbọ̀n mi;Èmi kò fi ojú mi pamọ́kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọsùtì sí.

7 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ràn mí lọ́wọ́;A kì yóò dójú tìmí.Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí Òkúta akọèmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.

8 Ẹni tí ó dámiláre wà nítòsí.Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀ṣùn kàn mí?Jẹ́ kí a kojú ara wa!Ta ni olùfisùn mi?Jẹ́ kí ó kòmí lójú!

9 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.Ta ni ẹni náà tí yóò dámí lẹ́bi?Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;kòkòrò ni yóò sì mú wọn jẹ.

10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwatí ó sì ń gbọ́ràn sí ìràńṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùntí kò ní ìmọ́lẹ̀,kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwakí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tannátí ẹ sì ń pèṣè iná ìléwọ́ fún ara yín,ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yínàti ti ìtùfú tí ẹ ti kánná lù.Ohun tí ẹ ó gbà lọ́wọ́ mi nìyìí:Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìpọ́njú.