Àìsáyà 39 BMY

Àwọn Ikọ̀ Ọba Láti Bábílónì

1 Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Heṣekáyà, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.

2 Heṣekáyà gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀ tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìpanǹkan mọ́ hàn wọn—sílífà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò fi hàn wọ́n.

3 Lẹ́yìn náà wòlíì Àìṣáyà lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?”“Láti ilẹ̀ jínjìnnà,” ni èsì Heṣekáyà. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Bábílónì.”

4 Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?”“Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Heṣekáyà. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fi hàn wọ́n.”

5 Lẹ́yìn náà ni Àìṣáyà sọ fún Heṣekáyà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun:

6 Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kó jọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkólọ sí Bábílónì. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí.

7 Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwọ̀fà nínú ààfin ọba Bábílónì.”

8 “Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ dára,” ni èsì Heṣekáyà. Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní Ìgbà ayé tèmi.”