Àìsáyà 58 BMY

Ààwẹ̀ Tòótọ́

1 “Kígbe rẹ̀ ṣókè, má ṣe fà ṣẹ́yìn.Gbé ohùn rẹ ṣókè bí i ti fèrè.Jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún áwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọnàti fún ilé Jákọ́bù ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

2 Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nàtí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkanwọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.

3 ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’“Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ní ọjọ́ ààwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yínẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.

4 Ààwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,àti lílu ọmọnìkejì ẹni pẹ̀lú ẹṣẹ́ ìkà.Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìíkí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.

5 Ǹjẹ́ èyí ha ni irú ààwẹ̀ tí mo yàn bí,ọjọ́ kanṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?Í haá ṣe kí ènìyàn tẹ orí i rẹ̀ ba bí i koríko láṣán ni bíàti ṣíṣùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ nìyí,ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

6 “Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodoàti láti tú gbogbo okùn àjàgà,láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?

7 Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń paàti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòsì tí ń rìn káàkirinígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòòhò, láti daṣọ bò ó,àti láti má ṣe lé àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran yín sẹ́yìn?

8 Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájúù rẹ,ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.

9 Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.“Bí ẹ̀yin bá mú àjàgà aninilára kúrò,pẹ̀lú ìka àléébù nínà àti ọ̀rọ̀ ìṣáátá,

10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń patí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,àti òru yín yóò dàbí ọ̀ṣán-gangan.

11 Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;òun yóò tẹ́ gbogbo àìní ìn yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí òòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀yóò sì fún egungun rẹ lókun.Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáadáa,àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í tán.

12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ róa ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wóàti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú un rẹ̀.

13 “Bí ìwọ bá pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́-ìsinmi jẹ́,àti síse bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùnàti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọàti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbíkí o máa ṣọ̀rọ̀ òòrayè,

14 nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ,èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,àti láti máa jàdídùn ìní tiJákọ́bù baba rẹ.”Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.