Àìsáyà 41 BMY

Olùrànlọ́wọ́ Fún Ísírẹ́lì

1 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájúù mi ẹ̀yin erékùṣù!Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè tún agbára wọn ṣe!Jẹ́ kí wọn wá ṣíwájú kí wọn sọ̀rọ̀:Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.

2 “Ta ni ó ti ru ẹnìkan ṣókè láti ìlà-oòrùn wá,tí ó pè é ní òdodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?Ó gbé àwọn orílẹ̀ èdè lé e lọ́wọ́ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájúu rẹ̀.Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,láti kù ú níyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.

3 Ó ń lé pa wọn ó sì tẹ̀ṣíwájú láì farapa,ní ojú ọ̀nà tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí.

4 Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹnì kìn-ín-ní wọnàti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi ni ẹni náà.”

5 Àwọn erékùsù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.Wọ́n súnmọ́tòsí wọ́n sì wá síwájú

6 Èkínní ran èkejì lọ́wọ́ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé“Jẹ́ alágbára!”

7 Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,àti ẹni tí ó fi òòlù dán anmú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”Ó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.

8 “Ṣùgbọ́n ìwọ, Ìwọ Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ mi,Jákọ́bù, ẹni tí mo ti yàn,ẹ̀yin ìran Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ mi,

9 mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

10 Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹni yẹ̀yẹ́;gbogbo àwọn tí ó lòdì sí ọyóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀ta rẹ,ìwọ kì yóò rí wọn.Gbogbo àwọn tí ó gbógun tì ọ́yóò dàbí òfuuru gbádá.

13 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mútí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

14 Ìwọ má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù kòkòrò,Ìwọ Ísírẹ́lì kékeré,nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”ni Olúwa wí,olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà,tuntun tí ó mú ti eyín rẹ̀ mu, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.

16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,àti ẹ̀fúùfù yóò sì gbá wọn dànùṢùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwaìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.

17 “Àwọn talákà àti aláìní wá omi,ṣùgbọ́n kò sí;ahọ́n wọn ṣáàápá fún òrùngbẹ.Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní àwọnibi gíga pọ́nyán ún,àti oríṣun omi ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,àti ilẹ̀ tí ó ṣáàápá yóò di orísun omi.

19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀igi kédárì àti akaṣíà, mítílì àti ólífì.Èmi yóò da páínì sí inú ilẹ̀ síṣá,igi fíri àti ṣípírẹ́ṣì papọ̀

20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti dá èyí.

21 “Mú ẹjọ́ wá,” ni Olúwa wí.“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jákọ́bù wí

22 “Mú àwọn ère-òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún waohun tí yóò ṣẹlẹ̀.Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọnkí àwa sì mọ àbájáde wọn níparí.Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,

23 ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dáníkí àwa kí ó lè mọ̀ pé Ọlọ́run niyín.Ẹ ṣe nǹkankan, ìbáà ṣe rere tàbí búburú,tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.

24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko já sí nǹkankaniṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.

25 “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọẹnìkan láti ìlà oòrùn tí ó pe orúkọ mi.Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.

26 Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀,tí àwa kò bá fi mọ̀,tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé,‘Òun sọ òtítọ́’?Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,ẹnikẹ́ni kò sàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

27 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Ṣíhóńì pé,‘Wò ó, àwọn nìyìí!’Mo fún Jérúsálẹ́mù ní ìránṣẹ́ ìhìn ayọ̀ kan.

28 Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.

29 Kíyèsí i, irọ́ ni gbogbo wọn!Gbogbo ìṣe wọn já sí asán;àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fúnafẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.