Àìsáyà 18 BMY

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Kúṣì

1 Ègbé ni fún ìwọ ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́,ní àwọn ipadò Kúṣì,

2 tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí òkunlórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi kóríko ṣe.Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀-ara wọn jọ̀lọ̀,sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,orílẹ̀ èdè aláfojúdi alájèjì èdè,tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

3 Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,nígbà tí a bá gbé àṣíá kan ṣókè lórí òkè,ẹ ó rí i,nígbà tí a bá fun fèrè kanẹ ó gbọ́ ọ.

4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ ẹ́, n ó sì máa wo òréréláti ibùgbé e mi wá,gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànsán òòrùn,gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárin gbùngbùn ìkóórè.”

5 Nítorí, kí ìkóórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tíìtànná kò sí mọ́,nígbà tí ìtànná di èso tí ó ń pọ́n bọ̀.Òun yóò sì fi ọ̀bẹ ìwẹgi gé àwọ ìsó tuntun kúrò,yóò sì gé àwọn ẹ̀ka tí ó ńgbilẹ̀ lulẹ̀ a sì kó wọn dànù.

6 Gbogbo wọn la ó fi lé àwọn jẹran jẹran ẹyẹlọ́wọ́ lórí òkèàti fún àwọn ẹranko búburú;àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣoúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùnàti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

7 Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogunláti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran ara wọn jọ̀lọ̀,láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,orílẹ̀ èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Síónì, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.