Àìsáyà 17 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìmọ̀ Kan Sí Dámásíkù

1 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dámásíkù:“Kíyèsíí, Dámásíkù kò ní jẹ́ ìlú mọ́ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

2 Àwọn ìlú Áróérì ni a ó kọ̀ sílẹ̀fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn ṣíbẹ̀,láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

3 Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Éfáímù,àti agbára ọba kúrò ní Dámásíkù;àwọn àsẹ́ku Árámù yóò dágẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Ísírẹ́lì,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

4 “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jákọ́bù yóò ṣá;ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

5 Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkóórè kó àwọnirúgbìn tí ó dúró jọtí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Réfémù.

6 Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi ólífì,tí èṣo ólífì méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kùsórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,mẹ́rin tàbí márùn ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

7 Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójúsókè sí Ẹlẹ́dàá wọnwọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ọ wọn,wọn kò sì ní kọbi ara sí òpó Áṣérà mọ́tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára wọn, tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, yóò dàbí ilẹ̀ tí a dà sílẹ̀ kó di ìgbòrò. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10 Ẹ ti gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà yín;ẹ kò sì rántí àpáta náà, àní odi agbára yín.

11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àsàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hú jáde,àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́nẹ mú kí wọ́n rúdí,ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìkóórè kò ní mú nǹkan wání ọjọ́ àrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

12 Kíyèsii, ìrunú àwọn orílẹ̀ èdè—wọ́n ń runú bí ìgbì òkun!Kíyèsii, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyànwọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń búramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n ṣálọ jìnnà réré,a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

14 Ní ihà, ìpayà òjijì!Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.