Àìsáyà 25 BMY

Ẹ Yin Olúwa

1 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run un mi;Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sìfi ìyìn fún orúkọọ̀ rẹnítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́o ti ṣe ohun ńlá,àwọn ohun tí o ti gbèròo rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

2 Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,ìlú olódi ti di ààtàn,ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;a kì yóò tún un kọ́ mọ́.

3 Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóòbọ̀wọ̀ fún ọ;àwọn ìlú orílẹ̀ èdè aláìláàánúyóò bọlá fún ọ.

4 Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòsìààbò fún aláìní nínú ìpọ́njúu rẹ̀ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjìbòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.Nítorí pé èémí àwọn ìkàdàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5 àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní ihà.O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,gẹ́gẹ́ bí òjìji kùrukùru ṣe ń dín ooru kù,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

6 Ní ori òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò ti pèṣèàṣè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyànàpèjẹ ti wáìnì àtijọ́ti ẹran tí ó dára jù àti ti wáìnìtí ó gbámúṣé.

7 Ní orí òkè yìí ni yóò parunaṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀;

8 Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. Olúwa gbogbo ayé yóò sì nu gbogbo omijé nù,kúrò ní ojúu gbogbo wọn;Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn an rẹ̀ kúròní gbogbo ilẹ̀ ayé. Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú un rẹ̀, òun sì gbà wá là.Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú un wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

10 Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìíṣùgbọ́n a ó tẹ Móábù mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀;gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11 Wọn yóò na ọwọ́ọ wọn jáde nínú un rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ọ rẹ̀jáde láti lúwẹ̀ẹ́.Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ọwọ́ ọ wọn.

12 Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀wọn yóò sì wà nílẹ̀Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,àní sí erùpẹ̀ lásán.