Àìsáyà 8 BMY

Ásíríà, Ohun-èlò Olúwa

1 Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi pẹ́ẹ́nì lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì:

2 Èmi yóò sì pe Hùráyà, Àlùfáà àti Ṣekaráyà ọmọ Jébérékíà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbọ́kànlé fún mi.

3 Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì-obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì.

4 Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Dámásíkù àti ìkógun ti Ṣamáríà ni ọba àwọn Áṣíríà yóò ti kó lọ.”

5 Olúwa sì tún sọ fún mi pé:

6 Nítorí pé àwọn ènìyàn ti kọomi Ṣílóà tí ń ṣàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́tí wọ́n sì láyọ̀ lórí Réṣínìàti ọmọ Rẹ̀málíà,

7 fún ìdí èyí, Olúwa fẹ́ mú wá sóríi wọnagbára ìkún omi odòọba Ásíríà àti ògo rẹ̀yóò sì bo gbogbo àyasíi rẹ̀gbogbo bèbè di bíbò mọ́lẹ̀

8 yóò sì gbá rìẹrìẹ dé Júdà, a gba orí ẹ̀ lọ,yóò gba ibẹ̀ lọ yóò sì mú un dọ́run.Ìyẹ́ apá rẹ̀ tí ó nà yóò bo gbogbo ìbú ilẹ̀ náàÌwọ Ìmánúẹ́lì.

9 Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ọ yín túútúúú,fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jínjìn réré.Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúúú!

10 Ẹ hun ète yín, yóò di títúká.Ẹ gbérò ètò náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lúu wa.

Bẹ̀rù Ọlọ́run

11 Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:

12 “Má ṣe pe éyí ní ọ̀tẹ̀ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá pè ní ọ̀tẹ̀,má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,má sì ṣe fòyà rẹ̀.

13 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,Òun ni kí o bẹ̀rùÒun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

14 Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ṣùgbọ́n fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọṣẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn ṣubúàti fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni yóò jẹ́ tàkúté àti ẹ̀bìtì.

15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọṣẹ̀,wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”

16 Di májẹ̀mú náàkí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.

17 Èmi yóò dúró de Olúwa,ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jákọ́bù.Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.

18 Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òké Síhónì.

19 Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn Oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè?

20 Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ní ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.

21 Pẹ̀lú ìpọ́njú àti ebi, ni wọn yóò máa rin ilẹ̀ náà ká, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni inú yóò bí wọn, wọn yóò síjú wòkè, wọn yóò sì ṣépè lé àwọn ọba àti ọlọ́run wọn.

22 Nígbà náà ni wọn yóò síjú wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúúrù tí ó bani lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.