Àìsáyà 46 BMY

Àwọn Ọlọ́run Bábílónì

1 Bẹ́lì tẹríi rẹ̀ ba, Nébò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti diàjàgà sí wọn lọ́rùn,ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.

2 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;wọn kò lè gba ẹrù náà,àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.

3 “Tẹ́tí sími ìwọ ilé Jákọ́bù,Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Ísírẹ́lì,Ìwọ tí mo ti gbérò láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.

4 Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú oríi yínÈmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.

5 “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mití àwa yóò jọ farawéra?

6 Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọnwọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n;wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,wọn sì tẹríba láti sìn ín.

7 Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.Láti ibẹ̀ náà kò le è paradàBí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.

8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.

9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́tijọ́;Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlọ̀mìíràn;Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmìíràn bí ì mi.

10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.Mo wí pé: Ète mi yóò dúró,àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.

11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò múṣẹ;èyí tí mo ti gbérò, òun ni èmi yóò ṣe.

12 Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọlọ́kàn-dídi,ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.

13 Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí,kò tilẹ̀ jìnnà rárá;àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró.Èmi yóò fún Ṣíhónì ní ìgbàlàògo mi fún Ísírẹ́lì.