Àìsáyà 62 BMY

Orúkọ Ṣíhónì Tuntun

1 Nítorí Ṣíhónì èmi kì yóò dákẹ́,nítorí i Jérúsálẹ́mù èmi kì yóò sinmi ẹnu,títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,àti ìgbàlà rẹ̀ bí i tọ́ọ̀sì tí ń jó geregere.

2 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò rí òdodo rẹ,àti gbogbo ọba ògo rẹa ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìírànèyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.

3 Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.

4 Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà,àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà;nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọàti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.

5 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwóbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwóGẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ.

6 Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù;wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi,

7 àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmitítí tí yóò fi fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀tí yóò sì fi òun ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.

8 Olúwa ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀àti nípa agbára apá rẹ:“Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹdi oúnjẹ fún ọ̀tá rẹbẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnìtuntun rẹ mọ́èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;

9 ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́tí wọn ó sì yin Olúwa,àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú unnínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”

10 Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó!Ẹ sa òkúta kúròẸ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè

11 Olúwa ti ṣe ìkédetítí dé òpin ilẹ̀ ayé:“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé,‘kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀,àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”

12 A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,ẹni ìràpadà Olúwa;a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀.