Àìsáyà 56 BMY

Ìgbàlà Fún Àwọn Mìíràn

1 Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsíàti òdodo mi ni a ó fi hàn láìpẹ́ jọjọ.

2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,ọkùnrin náà tí ó dì í mú ṣinṣin,tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bàá jẹ́,tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀mọ́ Olúwa sọ wí pé,“Olúwa yóò yà mí ṣọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”Àti kí ìwẹ̀fà kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

4 Nítorí pé ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mití wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹ́ḿpìlì àti àgbàlá rẹ̀ìrántí kan àti orúkọ kantí ó sànju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinÈmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayétí a kì yóò ké kúrò.

6 Àti àwọn àjèjì tí ó ṣo ara wọn mọ́ Olúwaláti sìn ín,láti fẹ́ orúkọ Olúwaàti láti foríbalẹ̀ fún ungbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

7 àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mièmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọnni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi;nítorí a ó máa pe ilé mi níilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè.”

8 Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé—ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Ísírẹ́lì jọ:“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lúu wọnyàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ.”

Ẹ̀ṣùn Tí Ọlọ́run Fi Kan Àwọn Ìkà

9 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú un pápá,ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

10 Àwọn olùṣọ́ Ísírẹ́lì fọ́jú,gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,wọn kò lè gbó;wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.

11 Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;wọn kì í ní ànító.Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò ní òye;olúkúlùkù ń yà sọ́nà ara rẹ̀,ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.

12 “Wá,” ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, “fún mi ní ọtí wáìnì!Jẹ́ kí a mu ọtí bíà wa lámu yóọ̀la yóò sì dàbí òní,tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”