Àìsáyà 35 BMY

Ayọ̀ Àwọn Ẹni Ìràpadà

1 Aṣálẹ̀ àti ìyàngbẹ ilẹ̀ ni inú rẹ̀ yóò dùn;ihà yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná.Gẹ́gẹ́ bí ewéko kúrókúsì,

2 òun yóò bẹ́ná jáde;yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kígbe fún ayọ̀.Ògo Lẹ́bánónì ni a ó fi fún un,ọlá ńlá Kámẹ́lì àti Ṣárónì;wọn yóò rí ògo Olúwa,àti ọlá ńlá Ọlọ́run wa.

3 Fún ọwọ́ àìlera lókun,mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:

4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé“Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù;Ọlọ́run yín yóò wá,òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan;pẹ̀lú ìgbẹ̀ṣan mímọ́òun yóò wá láti gbà yín là.”

5 Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́júàti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.

6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín,àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀.Odò yóò tú jáde nínú ihààti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.

7 Yanrìn tí ń jóná yóò di adágúnilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi.Òpópó ibi tí àwọn ajáko sùn tẹ́lẹ̀ríkoríko àti koríko odò àti ewéko mìíràn yóò hù níbẹ̀.

8 Àti opópónà kan yóò wà níbẹ̀:a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà-Mímọ́.Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà;yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náààwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.

9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀,tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lóríi rẹ̀;a kì yóò rí wọn níbẹ̀.Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,

10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin;ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí.Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn,ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.