Àìsáyà 16 BMY

1 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùnránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,Láti Ṣẹ́là, kọjá ní ihà,lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Ṣíhónì.

2 Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ẹ̀rẹ̀ǹbalẹ̀tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Móábùní àwọn ọmọdo Ánónì.

3 “Fún wa ní ìmọ̀rànṣe ìpinnu fún wa.Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru—ní ọ̀sán gangan.Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,má ṣe tú àwọn aṣàtìpó fó

4 Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Móábù gbé pẹ̀lúù rẹ,jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”Aninilára yóò wá sí òpin,ìparun yóò dáwọ́;òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

5 Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lóríi rẹ̀—ọ̀kan láti ilé Dáfídì wá.Ẹni nní ti ìdájọ́ ń wá ẹ̀tọ́tí ó sì fi ìyára wá ohun tí í ṣe òdodo.

6 Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù—Wábiwọ́sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,gààrùu rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀—ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

7 Nítorí náà ni àwọn ará Móábù pohùnréréwọ́n jùmọ̀ pohùnréré lórí Móábù.Ṣunkún kí o sì banújẹ́fún àwọn ọkùnrin ìlú Hárésétì.

8 Gbogbo pápá-oko Héṣíbónì ti gbẹ,bákan náà ni àjàrà Ṣíbínà rí.Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀ èdèwọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,èyí tí ó ti fà dé Jáṣérìó sì ti tàn dé agbègbè aṣálẹ̀.Àwọn èhu rẹ̀ fọ́n jádeó sì lọ títí ó fi dé òkun.

9 Nítorí náà mo ṣunkún, gẹ́gẹ́ bí Jáṣérì ṣe ṣunkún,fún àwọn àjàrà Ṣíbínà.Ìwọ Hẹ́ṣíbónì, Ìwọ Élíálẹ̀,mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!Igbe ayọ̀ lórí àwọn èṣo pípọ́n rẹàti lórí ìkóórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.

10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrònínú ọgbà-igi eléso rẹ;kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbíkígbe nínu ọgbà-àjàrà:ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.

11 Ọkàn mi kérora fún Móábù gẹ́gẹ́ bí i hápù,àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Háréṣétì.

12 Nígbà tí Móábù farahàn ní ibi gíga rẹ̀,ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúràòfo ni ó já sí.

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Móábù.

14 Ṣùgbọn ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrin ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, Ògo Móábù àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó ṣálà nínú un rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”