Àìsáyà 40 BMY

Ìtùnnú Fún Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run

1 Ẹ tùú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,ni Ọlọ́run yín wí.

2 Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jérúsálẹ́mùkí o sì kéde fún unpé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,pé à ti san gbésè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwaìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

3 Ohùn ẹnìkan tí ń pè:“Nínú ihà ẹ pèṣèọ̀nà sílẹ̀ fún Olúwa:ṣe é kí ó tọ́ ní ihàòpópónà fún Ọlọ́run wa.

4 Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé ṣókè,gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àtiọ̀nà pálapàla ni a yóò sọ di títẹ́jú pẹrẹṣẹ,

5 Ògo Olúwa yóò sì di mímọ̀gbogbo ọmọnìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rii.Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

6 Ohùn kan wí pé, “Kígbe ṣókè.”Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná inú un pápá.

7 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.

8 Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

9 Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Ṣíhónì,lọ sí orí òkè gíga.Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù,gbé ohùn rẹ ṣókè pẹ̀lú ariwo,gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;sọ fún àwọn ìlúu Júdà,“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

10 Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jọba fún un.Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

11 Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́.

12 Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?

13 Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14 Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹàti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́ntàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?

15 Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀ èdè dàbí i ẹ̀kán-ominínú garawa;a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.

16 Lẹ́bánónì kò tó fún pẹpẹ iná,tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.

17 Níwájúù rẹ ni gbogbo orílẹ̀ èdè dàbí ohun tí kò sí;gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlòtí kò tó ohun tí kò sí.

18 Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19 Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ótí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

20 Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

21 Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀ìwọ kò tí ì gbọ́?A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpilẹ̀ ayé?

22 Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé,àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

23 Ó sọ àwọn ọmọ ọba di aṣánàti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

24 Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,kété tí a gbìn wọ́n,kété tí wọ́n tita ẹ̀kan nínú ilẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,bẹ́ ni ìji-líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.

25 “Ta ni ẹ ó fi mi wé?Tàbí ta ni ó bámi dọ́gba?” ni Ẹni-Mímọ́ wí.

26 Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kantí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,ọ̀kanṣoṣo nínú wọn kò sọnù.

27 Èéṣe tí o fi sọ, Ìwọ Jákọ́bùàti tí o ṣàròyé, Ìwọ Ísírẹ́lì;“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;ìṣe mi ni a kò kọbi ara síláti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

28 Ìwọ kò tí ì mọ̀?Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé.Òun kì yóò ṣàárẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì,àti ìmọ̀ rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdiwọ̀n rẹ̀.

29 Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ó sì fi kún agbára àwọn aláàárẹ̀.

30 Àní àwọn ọ̀dọ́ ń rẹ̀wẹ̀sì, ó ń rẹ̀ wọ́n,àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

31 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwayóò tún agbára wọn ṣe.Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;wọn yóò ṣáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.