Àìsáyà 48 BMY

Ísírẹ́lì Olóríkunkun

1 “Tẹ́tí sí èyí, Ìwọ ilée Jákọ́bù,ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Ísírẹ́lìtí o sì wá láti ẹ̀ka Júdà,ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwatí o sì ń pe Ọlọ́run Ísírẹ́lìṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo

2 Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nìtí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Ísírẹ́lì— Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀:

3 Èmi sọ àṣọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mímọ̀;Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbéṣẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.

4 Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n;iwájúu yín idẹ ni

5 Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i.’

6 Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọnǸjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí?“Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọfún ọ nípa nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀.

7 A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’

8 Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bíláti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.

9 Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò.

10 Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

11 Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyíBáwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn.

Ísírẹ́lì Dòmìnira

12 “Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bùÍsírẹ́lì ẹni tí mo pè:Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.

13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.

14 “Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí:Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹló ti sọ nǹkan wọ̀nyí?Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwani yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì;apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.

15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.

16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;ní àṣìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”Àti ní àkókò yìí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ti rán mi,pẹ̀lú ẹ̀mii rẹ̀.

17 Èyí ni ohun tí Olúwa wíOlùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.

18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tísílẹ̀ sí àṣẹ mi,àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,àti òdodo rẹ bí ìgbì òkun.

19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí i yanrìn,àwọn ọmọ yín bí i horo ọkà tí a kò lè kà tán;orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúròtàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

20 Fi Bábílónì sílẹ̀,sá fún àwọn ará Bábílónì,ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀kí o sì kéde rẹ̀.Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jákọ́bù nídè.”

21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọnkọjá nínú ihà;ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;ó fọ́ àpátaomi sì tú jáde.

22 “Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,“Fún àwọn ìkà.”