Àìsáyà 21 BMY

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Bábílónì

1 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan ihà lẹ́bàá òkun:Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní ilẹ̀ ní gúṣù,akógunjàlú kan wá láti ihà,láti ilẹ̀ ìpayà.

2 Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fi hàn míọlọ̀tẹ̀ ti tasírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.Élámù kojújà! Mẹ́díà ti tẹ̀gùn!Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin,ni ó búra.

3 Pẹ̀lú èyí, ìrora kómi lára gírígírí,ìrora gbámimú, gẹ́gẹ́ bí i tiobìnrin tí ń rọbí,Mo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,ọkàn mi pòrúúrù nípa ohun tí mo rí.

4 Ọkàn mí dàrú,ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,tanmọóko tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ ríti wá di ìpayà fún mi.

5 Wọ́n tẹ́ tábìlì,wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,wọ́n jẹ, wọ́n mu!Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin òṣìṣẹ́,ẹ kún aṣà yín!

6 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Lọ, kí o bojúwòdekí o sì jẹ́ kí ó wá sọ ohun tí ó rí.

7 Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,àwọn agun-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tàbí àwọn tí ó gun ràkúnmí,jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,àní ìmúra gidigidi.”

8 Báyìí ni alóre náà kígbe,“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, Olúwa mi, mo dúró ní ilé ìṣọ́,alaalẹ́ ni mo fi ń wà nípò mi.

9 Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìínínú kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.Ó sì mú ìdáhùn padà wá:‘Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú!Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ló fọ́nká lórí ilẹ̀!’”

10 Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,mo sọ ohun tí mo ti gbọ́láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Édómù

11 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dúmáhì:Ẹnìkan ké sí mi láti Séírì wá“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”

12 Alóre náà dáhùn wí pé,“Òwúrọ̀ súnmọ́tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrèkí o sì tún dẹ̀yìn padà wá.”

Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Sí Arábíyà

13 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Arábíyà:Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dídánítì,tí ó pàgọ́ sínú igbó Arábíyà,

14 gbé omi wá fún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ;ẹ̀yin tí ó ń gbé Tẹ́mà,gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.

15 Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,kúrò lọ́wọ́ ọrun tí ó lòàti kúrò nínú ìgbóná ogun.

16 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrin ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ayẹkẹ Kédárì yóò wá sí òpin.

17 Àwọn tafàtafà tí ó ṣálà, àwọn jagunjagun Kédárì kò ní tó nǹkan” Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ó ti sọ̀rọ̀.