Àìsáyà 31 BMY

Ègbé Ni Fún Àwọn Tí Ó Gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì

1 Ègbé ni fún àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ síÉjíbítì fún ìrànwọ́,tí wọn gbẹ́kẹ̀lée eṣintí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọnàti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,ṣùgbọ́n ti wọn kò bojúwo Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì n nì,tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.

2 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọgbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.

3 Ṣùgbọ́n ènìyàn ṣáà ni àwọn ará Éjíbítìwọn kì í ṣe Ọlọ́run;ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde,ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọṣẹ̀,ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.

4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í kéàní kìnnìún ńlá lórí ẹranànjẹ rẹ̀bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàntí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojúu rẹ̀,ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọnakitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wáláti jagun lórí òkè Ṣíhónì àti lórí ibi gíga rẹ̀.

5 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò Jérúsálẹ́mù,Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”

6 Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.

7 Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ẹ yín ti ṣe.

8 “Ásíríà yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.Wọn yóò sì sá níwájú idà náààti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.

9 Ibi gíga wọn ni yóò wó lulẹ̀ nítorí ìpayà;nípa ìrísí agbára ogun wọn, àwọnọ̀gágun wọn yóò wárìrì,”ni Olúwa wí,ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Ṣíhónì,ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jérúsálẹ́mù.