12 Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,ta ni ó bèèrè èyí lọ́wọ́ ọ yín,Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
13 Ẹ má mú ọrẹ aṣán wá mọ́!Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,oṣù tuntun, ọjọ́ ọ̀sẹ̀ àti àwọn àpèjọÈmi kò lè faradà àpèjọ ibi yín wọ̀nyí.
14 Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àpèjẹtí ẹ yà ṣọ́tọ̀ni ọkàn mi kórìíra.Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,Ó ti sú mi láti máa fara dà wọ́n.
15 Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà,Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,Èmi kò ni tẹ́ti sí i.Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
16 Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
17 kọ́ láti ṣe rere!Wá ìdájọ́ òtítọ́,tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,gbà ẹjọ́ opó rò.
18 “Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,”ni Olúwa wí.“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,wọn ó sì funfun bí i yìnyín,bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.