15 Nigbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sóke ni àdúrà,Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,Èmi kò ni tẹ́ti sí i.Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
16 Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
17 kọ́ láti ṣe rere!Wá ìdájọ́ òtítọ́,tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,gbà ẹjọ́ opó rò.
18 “Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,”ni Olúwa wí.“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,wọn ó sì funfun bí i yìnyín,bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.
19 Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
20 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,idà ni a ó fi pa yín run.”Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.
21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ ríṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!