21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ ríṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!
22 Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là.
23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,akẹgbẹ́ àwọn olè,gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn.
24 Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogunAlágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé:“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá min ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.
25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà,àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo.