24 Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogunAlágbára kanṣoṣo tí Ísírẹ́lì sọ wí pé:“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá min ó sì gbẹ̀ṣan lára àwọn ọ̀tá mi.
25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀sípò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”
27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Ṣíhónì padà,àti àwọn tí ó ronú pìwàdà pẹ̀lú òdodo.
28 Ṣùgbọn àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó pa runÀwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.
29 “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́èyí tí ẹ ní inú dídùn sía ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìítí ẹ ti yàn fúnra yín.
30 Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ tí,tàbí bí ọgbà tí kò ní omi.