4 Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,Ìran àwọn aṣebi,àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀wọn ti gan Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì,wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.
5 Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,gbogbo ọkan yín sì ti pòrúúru.
6 Láti àtẹ́lẹṣẹ̀ yín dé àtàrí yínkò sí àlàáfíà rárá,àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapaàti ojú egbò,tí a kò nùnù tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
7 Orílẹ̀-èdè yín dahoro,a dáná sun àwọn ìlú yín,oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ runlójú ara yín náà,ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tíàwọn àjèjì borí rẹ̀.
8 Ọmọbìnrin Ṣíónì ni a fi sílẹ̀gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,gẹ́gẹ́ bí àbá nínú oko ẹ̀gúsí,àti bí ìlú tí a dótì.
9 Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogunbá sẹ́ díẹ̀ kù fún wà,a ò bá ti rí bí Sódómù,a ò bá sì ti dàbí Gòmórà.
10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,ẹ̀yin aláṣẹ Sódómù,tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà!