Àìsáyà 10:12-18 BMY

12 Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.

13 Nítorí ó sọ pé:“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ọ̀ mi ni mo fi ṣe èyíàti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀ èdè kúrò,Mo sì ti kó ìṣúra wọn.Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.

14 Bí ènìyàn tií tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ọ̀ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè.Bí ènìyàn tii kó ẹyin tí a kọ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀ èdèkò sí èyí tí ó fapálupá,tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,tàbí kí ayùn fọnnu sí ẹni tí ó ń lò ó?Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,yóò rán àrùn ìrẹ̀dànù sóríàwọn akíkanjú jagunjagun,lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọgẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

17 Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì yóò di iná,ẹni Mímọ́ an wọn ahọ́n iná,ní ijọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì runàti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

18 Gbogbo ẹwà igbóo rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràágbogbo rẹ̀ ni yóò run pátapáta,gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó sàìṣàn ti í ṣòfò dànù.