26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Mídíánìní òkè Órébù,yóò sì gbé ọ̀páa rẹ̀ lé orí omigẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Éjíbítì.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrùu wọn kúrò ní èjìká a yín,àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yína ó fọ́ àjàgà náà,nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.
28 Wọ́n wọ Áíyátì,Wọ́n gba Mígírónì kọjáWọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mísímásì.
29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,“Àwa ó tẹ̀dó sí Gébà lóru yìí.”Rámà mì tìtìGíbíà ti Ṣọ́ọ̀lù sá lọ.
30 Kígbe ṣókè, ìwọ ọmọbìnrin GálímùDẹtísílẹ̀, Ìwọ LáíṣàÒpè Ánátótì.
31 Mádíménà ti fẹṣẹ̀ fẹ́ ẹÀwọn ènìyàn Gébímù ti farapamọ́.
32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nóbùwọn yóò kan sáárá,ní òkè ọmọbìnrin Ṣíhónìní òkè Jérúsálẹ́mù.