13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókèga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpèjọní ṣónṣó orí òkè mímọ́.
14 Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọ̀sánmọ̀;Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ògo.”
15 Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọlọ sí ìṣàlẹ̀ ọ̀gbun.
16 Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtìtí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
17 Ẹni tí ó sọ ayé di aṣálẹ̀,tí ó dojú àwọn ìlú ńlá ńlá bolẹ̀tí kò sì jẹ́ kí àwọn ìgbèkùn padà sílé?”
18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojìgẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀,àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,àwọn tí idà ti gún,àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,