2 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbà wọ́nwọn yóò sì mú wọn wá sí àyèe wọn.Ilé Ísírẹ́lì yóò gba àwọn orílẹ̀ èdègẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrinní ilẹ̀ Olúwa.Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùnwọn yóò sì jọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
3 Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtùra fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà,
4 ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Bábílónì pé:Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
5 Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
6 èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdèpẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
7 Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,wọ́n bú sí orin.
8 Pẹ̀lú pẹ̀lù àwọn igi Páínì àti àwọnigi kédárì ti Lẹ́bánónìń yọ̀ lóríì rẹ ó wí pé,“Níwọ̀n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,kò sí alagi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”