1 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Éjíbítì:Kíyèsíi, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́sinó sì ń bọ̀ wá sí Éjíbítì.Àwọn ère òrìṣà Éjíbítì wárìrì níwájúu rẹ̀,ọkàn àwọn ará Éjíbítì sì ti domi nínú un wọn.
2 “Èmi yóò rú àwọn ará Éjíbítì sókè sí ara wọnarákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,aládúgbò yóò dìde sí aládúgbò rẹ̀,ìlú yóò dìde sí ìlú,ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.
3 Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù,èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀.
4 Èmi yóò fi Éjíbítì lé agbáraàwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,ọba aláìláàánú ni yóò jọba lé wọn lórí,”ni Olúwa, Olúwa Alágbára wí.