3 Àwọn ará Éjíbítì yóò sọ ìrètí nù,èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókúsọ̀rọ̀.
4 Èmi yóò fi Éjíbítì lé agbáraàwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,ọba aláìláàánú ni yóò jọba lé wọn lórí,”ni Olúwa, Olúwa Alágbára wí.
5 Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,gbogbo ilẹ̀ odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.
6 Àyasí omi yóò máa rùn;àwọn odò ilẹ̀ Éjíbítì yóò máa dínkùwọn yóò sì gbẹ.Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,
7 àwọn igi ìpadò Náì pẹ̀lú,tí ó wà ní oríṣun odò Náì.Gbogbo oko tí a dá sí ìpadò Náìyóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànùtí kò sì ní sí mọ́.
8 Àwọn apẹja yóò ṣunkún kíkorò,gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú Náí;yóò sì máa rùn.
9 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminúàwọn ahunsọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.