12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan nípamọ́fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíganítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀sílẹ̀),
13 nítorí gbogbo igi kedari Lẹ́bánónì, tó ga tó rìpóàti gbogbo óákù Báṣánì,
14 nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńláàti àwọn òkè kéé kèè kéé,
15 fún ilé ìṣọ́ gíga gígaàti àwọn odi ìdáàbòbò,
16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwòàwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí baa ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.