8 Báyìí ni alóre náà kígbe,“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, Olúwa mi, mo dúró ní ilé ìṣọ́,alaalẹ́ ni mo fi ń wà nípò mi.
9 Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀wá yìínínú kẹ̀kẹ́ ogunàti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.Ó sì mú ìdáhùn padà wá:‘Bábílónì ti ṣubú, ó ti ṣubú!Gbogbo àwọn ère òrìṣàa rẹ̀ló fọ́nká lórí ilẹ̀!’”
10 Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gúnmọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,mo sọ ohun tí mo ti gbọ́láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
11 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Dúmáhì:Ẹnìkan ké sí mi láti Séírì wá“Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”
12 Alóre náà dáhùn wí pé,“Òwúrọ̀ súnmọ́tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrèkí o sì tún dẹ̀yìn padà wá.”
13 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Arábíyà:Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dídánítì,tí ó pàgọ́ sínú igbó Arábíyà,
14 gbé omi wá fún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ;ẹ̀yin tí ó ń gbé Tẹ́mà,gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.