1 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ àfonífojì ti ìran:Kí ni ó ń dààmú un yín báyìí,tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ,
2 Ìwọ ìlú tí ó kún fún dàrúdàpọ̀,Ìwọ ìlú rúkèrúdò òun rògbòdìyànÀwọn tó ṣubú nínú un yín ni a kò fi idà pa,tàbí ojú ogun ni wọ́n kú sí.
3 Gbogbo àwọn olóríi yín ti jùmọ̀ sálọ;a ti kó wọn nígbékùn láì lo ọrun ọfà.Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀ta sì wàlọ́nà jínjìnréré.
4 Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:jẹ́ kí n ṣunkún kíkorò.Má ṣe gbìyànjú àti tùmí nínúnítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”