10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mùó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ìgànná lágbára.
11 Ìwọ mọ agbemi sí àárin ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbérò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn.
12 Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,pè ọ́ ní ọjọ́ náàláti ṣunkún kí o sì pohùnréré,kí o tu irun rẹ dànù kí o sìda aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
13 Ṣùgbọ́n Wòó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wàmàlúù pípa àti àgùntàn pípa,ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!“Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,” ni ẹ̀yin wí,“Nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”
14 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mímọ̀ létíì mi: “Títí di ọjọ́ ikúu yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
15 Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,fún Ṣébínà, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ọ rẹ̀:
16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti péta ni ó sì fún ọ ní àṣẹláti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí,tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gígatí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?