5 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kantí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ní àfonífojì ìmọ̀,ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀àti síṣun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
6 Élámù mú àpò-ọfà lọ́wọ́,pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,kírí yọ apata rẹ̀ síta.
7 Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́-ogun,àwọn ẹlẹ́ṣin ni a sọdó sí ẹnu bodè ìlú;
8 gbogbo ààbò Júdà ni a ti ká kúrò.Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náàsí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú ihà,
9 Ìwọ rí i pé ìlúu Dáfídìní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,ìwọ ti tọ́jú omisínú adágún ti ìsàlẹ̀.
10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mùó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ìgànná lágbára.
11 Ìwọ mọ agbemi sí àárin ògiri méjìfún omi inú adágún àtijọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ógbérò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn.